5. Rehoboamu ń gbé Jerusalẹmu, ó kọ́ àwọn ìlú ààbò wọnyi sí Juda:
6. Bẹtilẹhẹmu, Etamu, ati Tekoa;
7. Betisuri, Soko, ati Adulamu;
8. Gati, Mareṣa, ati Sifi;
9. Adoraimu, Lakiṣi, ati Aseka;
10. Sora, Aijaloni ati Heburoni. Àwọn ni ìlú olódi ní Juda ati Bẹnjamini.
11. Ó tún àwọn ìlú olódi ṣe, wọ́n lágbára, níbẹ̀ ni ó fi àwọn olórí ogun sí, ó sì kó ọpọlọpọ oúnjẹ, epo ati ọtí waini pamọ́ sibẹ.
12. Ó kó ọ̀kọ̀ ati apata sinu gbogbo wọn, ó sì fi agbára kún agbára wọn. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe fi ọwọ́ mú Juda ati Bẹnjamini.
13. Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli sì fara mọ́ Rehoboamu. Gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí wọ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.