Kronika Keji 11:12-15 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Ó kó ọ̀kọ̀ ati apata sinu gbogbo wọn, ó sì fi agbára kún agbára wọn. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe fi ọwọ́ mú Juda ati Bẹnjamini.

13. Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ Israẹli sì fara mọ́ Rehoboamu. Gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí wọ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀.

14. Àwọn ọmọ Lefi fi ilẹ̀ wọn sílẹ̀ ati ẹran ọ̀sìn wọn ati gbogbo ohun ìní wọn, wọ́n kó wá sí Juda, ati Jerusalẹmu; nítorí pé Jeroboamu ati àwọn ọmọ rẹ̀ lé wọn jáde, wọn kò jẹ́ kí wọ́n ṣe iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bí alufaa Ọlọrun.

15. Ó yan àwọn alufaa ti ara rẹ̀ fún ibi ìrúbọ ati fún ilé ère ewúrẹ́ ati ti ọmọ aguntan tí ó gbé kalẹ̀.

Kronika Keji 11