Kọrinti Kinni 7:23-25 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Iyebíye ni Ọlọrun rà yín. Ẹ má ṣe di ẹrú eniyan mọ́.

24. Ẹ̀yin ará, ipòkípò tí olukuluku bá wà tí a bá fi pè é, níbẹ̀ ni kí ó máa wà níwájú Ọlọrun.

25. N kò ní àṣẹ kan láti ọ̀dọ̀ Oluwa láti pa fún àwọn wundia. Ṣugbọn mò ń sọ ohun tí mo rò gẹ́gẹ́ bí ẹni tí Oluwa ti ṣàánú fún, tí eniyan sì lè gbẹ́kẹ̀lé.

Kọrinti Kinni 7