Kọrinti Kinni 5:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. A gbọ́ dájúdájú pé ìwà àgbèrè wà láàrin yín, irú èyí tí kò tilẹ̀ sí láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. A gbọ́ pé ẹnìkan ń bá iyawo baba rẹ̀ lòpọ̀!

2. Dípò èyí tí ọkàn yín ìbá fi bàjẹ́, tí ẹ̀ bá sì yọ ẹni tí ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kúrò láàrin yín, ẹ wá ń ṣe fáàrí!

5. ẹ fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ fún Satani, kí Satani lè pa ara rẹ̀ run, kí á lè gba ẹ̀mí rẹ̀ là ní ọjọ́ ìfarahàn Oluwa wa.

6. Fáàrí tí ẹ̀ ń ṣe kò dára! Ẹ kò mọ̀ pé ìwúkàrà díẹ̀ ni ó ń mú burẹdi wú sókè?

7. Ẹ mú ìwúkàrà àtijọ́ kúrò, kí ẹ lè dàbí burẹdi titun, ẹ óo wá di burẹdi titun ti kò ní ìwúkàrà ninu. Nítorí a ti fi Kristi ọ̀dọ́ aguntan Ìrékọjá wa rúbọ.

8. Nítorí náà ẹ jẹ́ kí á ṣe Àjọ̀dún Ìrékọjá wa, kì í ṣe burẹdi tí ó ní ìwúkàrà àtijọ́ ti ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà burúkú ni kí á fi ṣe é, ṣugbọn pẹlu burẹdi tí kò ní ìwúkàrà ninu, burẹdi ìwà mímọ́ ati òtítọ́.

9. Mo kọ ìwé si yín pé kí ẹ má ṣe darapọ̀ mọ́ àwọn tí ń hùwà ìbàjẹ́.

10. Kì í ṣe pé kí ẹ yẹra patapata fún àwọn alaigbagbọ tí ń hùwà àgbèrè, tabi tí ó ní ojúkòkòrò, tabi oníjìbìtì, tabi abọ̀rìṣà. Nítorí ẹ óo níláti jáde kúrò ninu ayé tí ẹ kò bá bá irú àwọn wọnyi lò.

Kọrinti Kinni 5