1. Bí ó ti yẹ kí eniyan máa rò nípa wa ni pé a jẹ́ iranṣẹ Kristi ati ìríjú àwọn nǹkan àṣírí Ọlọrun.
2. Ohun tí à ń retí lọ́dọ̀ ìríjú ni pé kí ó jẹ́ olóòótọ́.
3. Kò ṣe mí ní nǹkankan bí ẹ bá ń dá mi lẹ́jọ́ tabi bí ẹnikẹ́ni bá ń dá mi lẹ́jọ́. Èmi fúnra mi kì í tilẹ̀ dá ara mi lẹ́jọ́.
4. Ọkàn mi mọ́, ṣugbọn n kò wí pé mo pé, Oluwa ni ẹni tí ó ń ṣe ìdájọ́ mi.
5. Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe ìdájọ́ kí àkókò rẹ̀ tó tó, nígbà tí Oluwa yóo dé, tí yóo tan ìmọ́lẹ̀ sí ohun gbogbo tí ó fara pamọ́ sinu òkùnkùn, tí yóo mú kí gbogbo èrò ọkàn eniyan farahàn kedere. Nígbà náà ni olukuluku yóo gba iyìn tí ó yẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.
6. Ẹ̀yin ará, mo fi ara mi ati Apolo ṣe àpẹẹrẹ ohun tí à ń sọ nítorí yín, kí ẹ lè kọ́ ẹ̀kọ́ lára wa, pé kí ẹ má ṣe tayọ ohun tí ó wà ní àkọsílẹ̀. Ẹ kò gbọdọ̀ gbé ẹnìkan ga ju ẹnìkejì lọ.