Kọrinti Kinni 3:6-8 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Èmi gbin irúgbìn, Apolo bomi rin ohun tí mo gbìn, ṣugbọn Ọlọrun ni ó ń mú kí ohun ọ̀gbìn dàgbà.

7. Nítorí èyí, kì í ṣe ẹni tí ń gbin nǹkan, tabi ẹni tí ń bomi rin ín ni ó ṣe pataki, bíkòṣe Ọlọrun tí ó ń mú un dàgbà.

8. Ọ̀kan ni ẹni tí ó ń gbin irúgbìn ati ẹni tí ó ń bomi rin ín. Nígbà tí ó bá yá, ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn yóo gba èrè tirẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀ bá ti rí.

Kọrinti Kinni 3