Kọrinti Kinni 3:20-23 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Níbòmíràn, ó tún wí pé, “Oluwa mọ̀ pé asán ni èrò-inú àwọn ọlọ́gbọ́n.”

21. Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe tìtorí eniyan gbéraga, nítorí tiyín ni ohun gbogbo:

22. ati Paulu ni, ati Apolo, ati Peteru, ati ayé yìí, ati ìyè, ati ikú, ati àwọn nǹkan ìsinsìnyìí ati àwọn nǹkan àkókò tí ń bọ̀, tiyín ni ohun gbogbo.

23. Ṣugbọn ti Kristi ni yín, Kristi sì jẹ́ ti Ọlọrun.

Kọrinti Kinni 3