Kọrinti Kinni 13:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ǹ báà lè sọ oríṣìíríṣìí èdè tí eniyan ń fọ̀, kódà kí n tún lè sọ ti àwọn angẹli, bí n kò bá ní ìfẹ́, bí idẹ tí ń dún lásán ni mo rí; mo dàbí páànù tí wọn ń lù, tí ń hanni létí bí agogo.

2. Ǹ báà ní ẹ̀bùn wolii, kí n ní gbogbo ìmọ̀, kí n mọ gbogbo àṣírí ayé, kí n ní igbagbọ tí ó gbóná tóbẹ́ẹ̀ tí ó lè ṣí òkè ní ìdí, tí n kò bá ní ìfẹ́, n kò já mọ́ nǹkankan.

3. Ǹ báà kò gbogbo ohun tí mo ní, kí n fi tọrẹ, kódà kí n fi ara mi rú ẹbọ sísun, bí n kò bá ní ìfẹ́, kò ṣe anfaani kankan fún mi.

Kọrinti Kinni 13