1. Nípa ti ìrànlọ́wọ́ fún àwọn onigbagbọ, kò nílò pé kí n tún kọ ìwé si yín mọ́.
2. Nítorí mo mọ àníyàn yín, mo sì ti ń fi ọwọ́ sọ̀yà nípa yín fún àwọn ará Masedonia, pé Akaya ti parí ètò tiwọn láti ọdún tí ó kọjá. Ìtara yín sì ti mú kí ọpọlọpọ túbọ̀ múra sí i.
3. Mo rán àwọn arakunrin sí yín, kí ọwọ́ tí a fi ń sọ̀yà nípa yín lórí ọ̀rọ̀ yìí má baà jẹ́ lásán. Gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ, kí ẹ ti múra sílẹ̀.
4. Nítorí bí àwọn ará Masedonia bá bá mi wá sọ́dọ̀ yín, tí wọ́n wá rí i pé ẹ kò tíì múra sílẹ̀, ìtìjú ni yóo jẹ́ fún wa, kí á má wá sọ tiyín, nígbà tí a ti fi ọkàn tan yín lórí ọ̀rọ̀ yìí.
5. Nítorí náà, mo rí i pé ó di dandan pé kí n bẹ àwọn arakunrin láti ṣiwaju mi wá sọ́dọ̀ yín, kí wọ́n ṣe ètò sílẹ̀ nípa ẹ̀bùn tí ẹ ti ṣe ìlérí, kí ó jẹ́ pé yóo ti wà nílẹ̀ kí n tó dé. Èyí yóo mú kí ó jẹ́ ọrẹ àtinúwá, kò ní jẹ́ ti ìlọ́ni-lọ́wọ́-gbà.