Kọrinti Keji 7:11-13 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ṣé ẹ wá rí i bí ìbànújẹ́ tí ẹ faradà gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti fẹ́, ti yọrí sí fun yín? Ó mú kí ẹ fi ìtara mú ọ̀rọ̀ náà, kí ẹ sì jà fún ara yín. Ó mú kí inú bi yín sí ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Ó mú ìbẹ̀rù wá sọ́kàn yín. Ó mú kí ẹ ṣe aájò mi. Ó mú kí ẹ ní ìtara. Ó mú kí ẹ rí i pé ẹ ṣe ẹ̀tọ́ ninu ọ̀ràn náà. Ní gbogbo ọ̀nà ẹ ti fihàn pé ọwọ́ yín mọ́ ninu ọ̀ràn náà.

12. Nígbà tí mo kọ ìwé tí mo kọ́ kọ, kì í ṣe nítorí ti ẹni tí ó ṣe àìdára, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nítorí ti ẹni tí wọ́n ṣe àìdára sí. Ṣugbọn mo kọ ọ́ kí ìtara yín lè túbọ̀ hàn níwájú Ọlọrun.

13. Ìdí rẹ̀ nìyí tí a fi ní ìtùnú.Lẹ́yìn pé a ní ìtùnú, a tún ní ayọ̀ pupọ nígbà tí a rí bí ayọ̀ Titu ti pọ̀ tó, nítorí ọkàn rẹ̀ balẹ̀ láàrin gbogbo yín.

Kọrinti Keji 7