Kọrinti Keji 5:12-16 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Kò tún nílò pé kí á máa pọ́n ara wa fun yín mọ́. Ṣugbọn èyí yóo jẹ́ anfaani fun yín láti máa fi wá ṣògo, kí ẹ lè máa rí ohun wí fún àwọn tí wọn ń ṣògo nípa nǹkan ti òde ara, tí kì í ṣe nípa nǹkan ti inú ọkàn.

13. Bí ó bá dàbí ẹni pé orí wa kò pé, nítorí ti Ọlọrun ni. Bí a bá jẹ́ ọlọ́gbọ́n, a jẹ́ ẹ fun yín,

14. nítorí ìfẹ́ Kristi ni ó ń darí wa, nígbà tí a ti mọ̀ pé ẹnìkan ti kú fún gbogbo eniyan, a mọ̀ pé ikú gbogbo eniyan ni ó gbà kú.

15. Ìdí tí Kristi fi kú fún gbogbo eniyan ni pé kí àwọn tí ó wà láàyè má ṣe wà láàyè fún ara wọn, ṣugbọn kí wọ́n lè wà láàyè fún ẹni tí ó kú fún wa, tí Ọlọrun sì jí dìde.

16. Àyọrísí gbogbo èyí ni pé, láti ìgbà yìí lọ, àwa kò tún ní wo ẹnikẹ́ni ní ìwò ti ẹ̀dá mọ́. Nígbà kan ìwò ti ẹ̀dá ni à ń wo Kristi, ṣugbọn a kò tún wò ó bẹ́ẹ̀ mọ́.

Kọrinti Keji 5