25. Ẹẹmẹta ni a fi ọ̀pá lù mí. A sọ mí lókùúta lẹ́ẹ̀kan. Ẹẹmẹta ni ọkọ̀ ojú omi tí mo wọ̀ rì. Fún odidi ọjọ́ kan, tọ̀sán-tòru, ni mo fi wà ninu agbami.
26. Ní ọpọlọpọ ìgbà ni mo wà lórí ìrìn àjò, tí mo wà ninu ewu omi, ewu lọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà, ewu láàrin àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ mi, ewu láàrin àwọn tíí ṣe Juu, ewu ninu ìlú, ewu ninu oko, ewu lójú òkun, ati ewu láàrin àwọn èké onigbagbọ.
27. Mo ti rí ọ̀pọ̀ wahala ati ìṣòro. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni n kò lè sùn. Ebi pa mí, òùngbẹ gbẹ mí. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mò ń gbààwẹ̀. Mo mọ ìgbà òtútù ati ìgbà tí aṣọ kò tó láti fi bora.
28. Láì ka àwọn nǹkan mìíràn tí n kò mẹ́nubà, lojoojumọ ni àníyàn gbogbo àwọn ìjọ wúwo lọ́kàn mi.
29. Ta ni jẹ́ aláìlera tí n kò ní ìpín ninu àìlera rẹ̀? Ta ni ṣubú sinu ẹ̀ṣẹ̀ tí ọkàn mi kò bàjẹ́?
30. Bí mo bá níláti fọ́nnu, n óo fọ́nnu nípa àwọn àìlera mi.
31. Ọlọrun Baba Oluwa wa Jesu, ẹni tí ìyìn yẹ fún títí lae, mọ̀ pé n kò purọ́.
32. Ní Damasku, baálẹ̀ tí ó wà lábẹ́ Ọba Areta ń ṣọ́ ẹnu odi ìlú láti mú mi.
33. Apẹ̀rẹ̀ ni wọ́n fi sọ̀ mí kalẹ̀ láti ojú fèrèsé lára odi ìlú, ni mo fi bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.