21. Ojú tì mí láti gbà pé àwa kò lágbára tó láti hu irú ìwà bẹ́ẹ̀!Ṣugbọn bí ẹnìkan bá láyà láti fi ohun kan ṣe ìgbéraga, ẹ jẹ́ kí n sọ̀rọ̀ bí aṣiwèrè, èmi náà láyà láti ṣe ìgbéraga.
22. Ṣé Heberu ni wọ́n ni? Heberu ni èmi náà. Ọmọ Israẹli ni wọ́n? Bẹ́ẹ̀ ni èmi náà. Ṣé ìdílé Abrahamu ni wọ́n? Òun ni èmi náà.
23. Iranṣẹ Kristi ni wọ́n? Tí n óo bá sọ̀rọ̀ bí ẹni tí orí rẹ̀ kò pé, mo jù wọ́n lọ gẹ́gẹ́ bí iranṣẹ Kristi. Mo ti fi agbára ṣiṣẹ́ jù wọ́n lọ. Mo ti wẹ̀wọ̀n nígbà pupọ jù wọ́n lọ. Wọ́n ti nà mí nígbà pupọ jù wọ́n lọ. Ẹ̀mí fẹ́rẹ̀ bọ́ lẹ́nu mi ní ọpọlọpọ ìgbà.
24. Ẹẹmarun-un ni àwọn Juu nà mí ní ẹgba mọkandinlogoji.