14. Àwọn ọmọ Israẹli bá wọn jẹ ninu oúnjẹ wọn, wọn kò sì bèèrè ìtọ́sọ́nà lọ́dọ̀ OLUWA.
15. Joṣua bá wọn dá majẹmu alaafia, pé, àwọn kò ní pa wọ́n, àwọn àgbààgbà Israẹli sì búra fún wọn.
16. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹta tí wọ́n ti bá àwọn eniyan náà ṣe àdéhùn, ni wọ́n gbọ́ pé nítòsí wọn ni wọ́n wà, ati pé aládùúgbò ni wọ́n.
17. Àwọn ọmọ Israẹli bá gbéra ní ọjọ́ kẹta, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ka àwọn ìlú wọn. Àwọn ìlú náà ni: Gibeoni, Kefira, Beeroti ati Kiriati Jearimu.
18. Ṣugbọn àwọn ọmọ Israẹli kò pa wọ́n, nítorí pé àwọn àgbààgbà wọn ti búra fún wọn ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli. Gbogbo ìjọ eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí i kùn sí àwọn àgbààgbà.
19. Ṣugbọn gbogbo àwọn àgbààgbà dá ìjọ eniyan náà lóhùn pé, “A ti búra fún wọn ní orúkọ OLUWA Ọlọrun Israẹli, a kò sì gbọdọ̀ fọwọ́ kàn wọ́n mọ́.
20. Ohun tí a lè ṣe ni pé kí á dá wọn sí, kí ibinu OLUWA má baà wá sórí wa, nítorí ìbúra tí a ti ṣe fún wọn.”