12. Kì í ṣe idà tabi ọfà ni ẹ fi ṣẹgun àwọn ọba ará Amori mejeeji, agbọ́n ni mo rán ṣáájú yín tí ó sì lé wọn jáde fun yín.
13. Mo fun yín ní ilẹ̀ tí ẹ kò ṣe làálàá fún, ati àwọn ìlú ńláńlá, tí ẹ kò tẹ̀ dó, ẹ sì ń gbé ibẹ̀. Ẹ̀ ń jẹ èso àjàrà ati ti igi olifi tí kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbìn.’
14. “Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù OLUWA, kí ẹ sì máa sìn ín tọkàntọkàn pẹlu òtítọ́ inú. Ẹ kó gbogbo oriṣa tí àwọn baba yín ń bọ ní òdìkejì odò ati ní Ijipti dànù, kí ẹ sì máa sin OLUWA.
15. Bí kò bá wá wù yín láti máa sin OLUWA, ẹ yan ẹni tí ó bá wù yín láti máa sìn lónìí. Kì báà ṣe àwọn oriṣa tí àwọn baba yín ń bọ ní òdìkejì odò, tabi oriṣa àwọn ará Amori tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ wọn. Ṣugbọn ní tèmi ati ilé mi, OLUWA ni àwa óo máa sìn.”