Joṣua 22:32-34 BIBELI MIMỌ (BM)

32. Nígbà náà ni Finehasi ọmọ Eleasari, alufaa, ati àwọn olórí kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi, ní ilẹ̀ Gileadi; wọ́n pada lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Israẹli ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì jíṣẹ́ fún wọn.

33. Iṣẹ́ tí wọ́n jẹ́ náà dùn mọ́ àwọn ọmọ Israẹli ninu, wọ́n sì fi ìyìn fún Ọlọrun; wọn kò sì ronú ati bá wọn jagun mọ́, tabi àtipa ilẹ̀ wọn run níbi tí wọ́n ń gbé.

34. Àwọn ẹ̀yà Reubẹni ati ẹ̀yà Gadi bá pe pẹpẹ tí wọ́n tẹ́ ní, “Ẹ̀rí” nítorí wọ́n ní, “Pẹpẹ náà ni ẹ̀rí láàrin wa pé, OLUWA ni Ọlọrun.”

Joṣua 22