12. Nigba tí àwọn ọmọ Israẹli gbọ́ èyí, gbogbo wọ́n bá péjọ sí Ṣilo láti lọ bá wọn jagun.
13. Àwọn ọmọ Israẹli ranṣẹ sí ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase ní ilẹ̀ Gileadi, àwọn tí wọ́n rán ni Finehasi, ọmọ Eleasari, alufaa,
14. ati àwọn olórí mẹ́wàá; wọ́n yan olórí kọ̀ọ̀kan láti inú ìdílé Israẹli kọ̀ọ̀kan, olukuluku wọn sì jẹ́ baálé ninu ìdílé wọn.