27. Ninu ilẹ̀ ìdajì ẹ̀yà Manase ni wọ́n ti fún àwọn ọmọ Geriṣoni ninu ìdílé Lefi ní àwọn ìlú wọnyi: Golani ní ilẹ̀ Baṣani pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká rẹ̀. Golani yìí jẹ́ ìlú ààbò fún àwọn tí wọ́n bá ṣèèṣì pa eniyan, ati Beeṣitera pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká rẹ̀, wọ́n jẹ́ ìlú meji.
28. Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Isakari, wọ́n fún wọn ní: Kiṣioni, Daberati,
29. ati Jarimutu, Enganimu pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin.
30. Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Aṣeri, wọ́n fún wọn ní: Miṣali, Abidoni,
31. Helikati, ati Rehobu pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin.
32. Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Nafutali, wọ́n fún wọn ní: Kedeṣi ní Galili. Kedeṣi yìí jẹ́ ìlú ààbò fún àwọn tí wọ́n bá ṣèèṣì pa eniyan, wọ́n tún fún wọn ní Hamoti Dori, Katani pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹta.
33. Ìlú mẹtala ati pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn ni ilẹ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Geriṣoni, gẹ́gẹ́ bi iye ìdílé wọn.
34. Ìdílé tí ó ṣẹ́kù ninu ẹ̀yà Lefi ni ìdílé Merari. Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Sebuluni, wọ́n fún wọn ní: Jokineamu, Kata,
35. Dimna, Nahalali pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin.
36. Ninu ilẹ̀ ẹ̀yà Reubẹni, wọ́n fún wọn ní: Beseri, Jahasi,
37. Kedemotu, ati Mefaati pẹlu àwọn pápá ìdaran tí ó wà ní àyíká wọn, gbogbo wọn jẹ́ ìlú mẹrin.