18. Lórí ilẹ̀ náà ni àwọn ìlú wọnyi wà: Jesireeli, Kesuloti, Ṣunemu;
19. Hafaraimu, Sihoni, Anaharati;
20. Rabiti, Kiṣioni, Ebesi;
21. Remeti, Enganimu, Enhada, ati Betipasesi.
22. Ààlà ilẹ̀ náà lọ kan Tabori, Ṣahasuma ati Beti Ṣemeṣi, kí ó tó lọ pin sí odò Jọdani. Gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹrindinlogun.
23. Àwọn ni ìlú ati ìletò náà tí ó wà ninu ilẹ̀ tí ó kan ẹ̀yà Isakari gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.
24. Ilẹ̀ karun-un tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Aṣeri.
25. Ninu ilẹ̀ náà ni àwọn ìlú wọnyi wà: Helikati, Hali, Beteni, Akiṣafu.
26. Alameleki, Amadi, ati Miṣali, ní apá ìwọ̀ oòrùn, ilẹ̀ náà dé Kamẹli ati Ṣihori Libinati.