Joṣua 19:16-23 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Àwọn ni ìlú ati ìletò tí ó wà ninu ilẹ̀ tí ó kan ẹ̀yà Sebuluni gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

17. Ilẹ̀ kẹrin tí wọ́n ṣẹ́ gègé lé lórí bọ́ sí ọwọ́ ẹ̀yà Isakari.

18. Lórí ilẹ̀ náà ni àwọn ìlú wọnyi wà: Jesireeli, Kesuloti, Ṣunemu;

19. Hafaraimu, Sihoni, Anaharati;

20. Rabiti, Kiṣioni, Ebesi;

21. Remeti, Enganimu, Enhada, ati Betipasesi.

22. Ààlà ilẹ̀ náà lọ kan Tabori, Ṣahasuma ati Beti Ṣemeṣi, kí ó tó lọ pin sí odò Jọdani. Gbogbo ìlú ati ìletò wọn jẹ́ mẹrindinlogun.

23. Àwọn ni ìlú ati ìletò náà tí ó wà ninu ilẹ̀ tí ó kan ẹ̀yà Isakari gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn.

Joṣua 19