Ní apá ìhà àríwá, ààlà ilẹ̀ wọn bẹ̀rẹ̀ ní etí odò Jọdani, lọ sí ara òkè ní ìhà àríwá Jẹriko. Ó gba ààrin àwọn ìlú tí wọ́n wà ní orí òkè lọ ní apá ìwọ̀ oòrùn, ó sì pin sí aṣálẹ̀ Betafeni.