1. Nígbà tí Jabini ọba Hasori, gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó ranṣẹ sí Jobabu, ọba Madoni, ati sí ọba Ṣimironi, ati sí ọba Akiṣafu,
2. ati sí àwọn ọba tí wọ́n wà ní àwọn ìlú olókè ti apá ìhà àríwá, ati sí àwọn tí wọ́n wà ní Araba ní ìhà gúsù Kineroti, ati sí àwọn tí wọ́n wà ní ẹsẹ̀ òkè, ati sí àwọn tí wọ́n wà ní Nafoti-dori ní apá ìwọ̀ oòrùn.