8. Ṣugbọn kí gbogbo wọn fi aṣọ ọ̀fọ̀ bora, kí wọ́n sì fi gbogbo ọkàn wọn gbadura sí Ọlọrun. Kí olukuluku pa ọ̀nà burúkú ati ìwà ipá tí ó wà lọ́wọ́ rẹ̀ tì.
9. A kì í mọ̀, bóyá Ọlọrun lè yí ọkàn rẹ̀ pada, kí ó má jẹ wá níyà mọ́. Bóyá yóo tilẹ̀ dá ibinu rẹ̀ dúró, kò sì ní pa wá run.”
10. Nígbà tí Ọlọrun rí i pé wọ́n ti pa ìwà burúkú wọn tì, Ọlọrun náà bá yí ìpinnu rẹ̀ pada, kò sì jẹ wọ́n níyà mọ́.