4. Nígbà náà ni mo sọ pé,‘A ti ta mí nù kúrò níwájú rẹ;báwo ni n óo ṣe tún rí tẹmpili mímọ́ rẹ?’
5. Omi bò mí mọ́lẹ̀,ibú omi yí mi ká,koríko inú omi sì wé mọ́ mi lórí.
6. Mo já sí ibi tí ó jìn jùlọ ninu òkun,àní ibi tí ẹnikẹ́ni kò lọ ní àlọ-bọ̀ rí.Ṣugbọn ìwọ, OLUWA Ọlọrun mi,o mú ẹ̀mí mi jáde láti inú ibú náà.
7. Nígbà tí ẹ̀mí mi ń bọ́ lọ,mo gbadura sí ìwọ OLUWA,o sì gbọ́ adura mi ninu tẹmpili mímọ́ rẹ.
8. Àwọn tí wọn ń sin àwọn oriṣa lásánlàsàn kọ̀,wọn kò pa ìlérí wọn sí ọ mọ́.
9. Ṣugbọn n óo rúbọ sí ọ pẹlu ohùn ọpẹ́,n óo sì san ẹ̀jẹ́ mi.Ti OLUWA ni ìgbàlà!”
10. OLUWA bá pàṣẹ fún ẹja tí ó gbé Jona mì, ó sì lọ pọ̀ ọ́ sí èbúté, lórí ilẹ̀ gbígbẹ.