1. Jona gbadura sí OLUWA Ọlọrun rẹ̀ láti inú ẹja náà,
2. ó ní, “Ninu ìpọ́njú mi, mo ké pe OLUWA,ó sì dá mi lóhùn,mo ké pè é láti inú isà òkú, ó sì gbóhùn mi.
3. Nítorí pé, ó gbé mi jù sinu ibú, ní ààrin agbami òkun,omi òkun sì bò mí mọ́lẹ̀;ọwọ́ agbára rírú omi òkun rẹ̀ sì ń wọ́ kọjá lórí mi.
4. Nígbà náà ni mo sọ pé,‘A ti ta mí nù kúrò níwájú rẹ;báwo ni n óo ṣe tún rí tẹmpili mímọ́ rẹ?’
5. Omi bò mí mọ́lẹ̀,ibú omi yí mi ká,koríko inú omi sì wé mọ́ mi lórí.
6. Mo já sí ibi tí ó jìn jùlọ ninu òkun,àní ibi tí ẹnikẹ́ni kò lọ ní àlọ-bọ̀ rí.Ṣugbọn ìwọ, OLUWA Ọlọrun mi,o mú ẹ̀mí mi jáde láti inú ibú náà.
7. Nígbà tí ẹ̀mí mi ń bọ́ lọ,mo gbadura sí ìwọ OLUWA,o sì gbọ́ adura mi ninu tẹmpili mímọ́ rẹ.
8. Àwọn tí wọn ń sin àwọn oriṣa lásánlàsàn kọ̀,wọn kò pa ìlérí wọn sí ọ mọ́.