15. Ṣugbọn àwọn Juu kígbe pé, “Mú un kúrò! Mú un kúrò! Kàn án mọ́ agbelebu!”Pilatu sọ fún wọn pé, “Kí n kan ọba yín mọ́ agbelebu?”Àwọn olórí alufaa dá a lóhùn pé, “A kò ní ọba lẹ́yìn Kesari.”
16. Pilatu bá fa Jesu fún wọn láti kàn mọ́ agbelebu.Wọ́n bá gba Jesu lọ́wọ́ Pilatu.
17. Ó ru agbelebu rẹ̀ jáde lọ sí ibìkan tí ó ń jẹ́ “Ibi Agbárí,” tí wọn ń pè ní “Gọlgọta” ní èdè Heberu.
18. Níbẹ̀ ni wọ́n ti kàn án mọ́ agbelebu, òun ati àwọn meji kan, ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún, ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ òsì, Jesu wá wà láàrin.