Johanu 11:54-57 BIBELI MIMỌ (BM)

54. Nítorí náà, Jesu kò rìn ní gbangba mọ́ láàrin àwọn Juu, ṣugbọn ó kúrò níbẹ̀, ó lọ sí ìlú kan lẹ́bàá aṣálẹ̀, tí ó ń jẹ́ Efuraimu. Níbẹ̀ ni ó ń gbé pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

55. Nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ tó àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá ti àwọn Juu, ọ̀pọ̀ eniyan gòkè lọ sí Jerusalẹmu láti ìgbèríko, kí ó tó tó àkókò àjọ̀dún, kí wọ́n lè ṣe ìwẹ̀mọ́ fún àjọ̀dún náà.

56. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wá Jesu, wọ́n ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ bí wọ́n ti dúró ninu Tẹmpili pé, “Kí ni ẹ rò? Ǹjẹ́ ó jẹ́ wá sí àjọ̀dún yìí?”

57. Àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi ti pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni tí ó bá mọ ibi tí Jesu wà, kí ó wá sọ, kí wọ́n lè mú un.

Johanu 11