14. Ẹ̀yin baba, mo kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti mọ ẹni tí ó wà láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé. Ẹ̀yin ọdọmọkunrin, mo kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ lágbára, ọ̀rọ̀ Ọlọrun ń gbé inú yín, ẹ sì ti ṣẹgun Èṣù.
15. Ẹ má fẹ́ràn ayé tabi àwọn nǹkan ayé. Ẹni tí ó bá fẹ́ràn ayé kò ní ìfẹ́ sí Baba.
16. Nítorí gbogbo nǹkan tí ó wà ninu ayé: ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara, ìwòkúwò ojú ati afẹfẹyẹ̀yẹ̀ ayé kò wá láti ọ̀dọ̀ Baba bíkòṣe láti inú ayé.
17. Ayé ati ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ń kọjá lọ, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọrun yóo wà títí lae.
18. Ẹ̀yin ọmọde, àkókò ìkẹyìn nìyí! Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́ pé Alátakò Kristi ń bọ̀, nisinsinyii ọpọlọpọ àwọn alátakò Kristi ti ń yọjú. Èyí ni a fi mọ̀ pé àkókò ìkẹyìn nìyí.
19. Ọ̀dọ̀ wa ni wọ́n ti kúrò ṣugbọn wọn kì í ṣe ara wa. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé ara wa ni wọ́n, wọn ìbá dúró lọ́dọ̀ wa. Ṣugbọn kí ó lè hàn dájú pé gbogbo wọn kì í ṣe ara wa ni wọ́n ṣe kúrò lọ́dọ̀ wa.