Jobu 31:15-17 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Ṣebí ẹni tí ó dá mi ninu oyún,òun kan náà ló dá iranṣẹ mi?Òun ló mọ wá kí wọn tó bí wa.

16. “Bí mo bá fi ohunkohun pọ́n talaka lójú rí,tabi kí n fi opó sílẹ̀ ninu àìní,

17. tabi kí n dá oúnjẹ mi jẹ,láìfún ọmọ aláìníbaba jẹ

Jobu 31