13. “Bí mo bá kọ̀ láti fetí sí ẹjọ́ àwọniranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin mi,nígbà tí wọ́n bá fẹ̀sùn kàn mí,
14. báwo ni n óo ṣe dúró níwájú Ọlọrun?Kí ni kí n wí nígbà tí ó bá bèèrè lọ́wọ́ mi?
15. Ṣebí ẹni tí ó dá mi ninu oyún,òun kan náà ló dá iranṣẹ mi?Òun ló mọ wá kí wọn tó bí wa.
16. “Bí mo bá fi ohunkohun pọ́n talaka lójú rí,tabi kí n fi opó sílẹ̀ ninu àìní,
17. tabi kí n dá oúnjẹ mi jẹ,láìfún ọmọ aláìníbaba jẹ
18. (láti ìgbà èwe rẹ̀ ni mo ti ń ṣe bíi baba fún un,tí mo sì ń tọ́jú rẹ̀ láti inú ìyá rẹ̀);
19. bí mo bá ti rí ẹni tí ó ń kú lọ,nítorí àìrí aṣọ bora,tabi talaka tí kò rí ẹ̀wù wọ̀,
20. kí ó sì súre fún mi,nítorí pé ara rẹ̀ móorupẹlu aṣọ tí a fi irun aguntan mi hun,
21. bí mo bá fi ìyà jẹ aláìníbaba,nítorí pé mo mọ eniyan ní ilé ẹjọ́,
22. jẹ́ kí apá mi já kúrò léjìká mi,kí ó yọ ní oríkèé rẹ̀.
23. Nítorí ẹ̀rù ìpọ́njú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ń bà mí,nítorí ògo rẹ̀, n kò lè dán irú rẹ̀ wò.
24. “Bí mo bá gbójú lé wúrà,tí mo sì fi ojúlówó wúrà ṣe igbẹkẹle mi,
25. bí mo bá ń yọ̀ nítorí pé mo ní ọrọ̀ pupọ,tabi nítorí pé ọwọ́ mi ti ba ọpọlọpọ ohun ìní.
26. Tí mo bá ti wo oòrùn nígbà tí ó ń ràn,tabi tí mo wo òṣùpá ninu ẹwà rẹ̀: