Jobu 30:12-31 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Àwọn oníjàgídíjàgan dìde sí mi ní apá ọ̀tún mi,wọ́n lé mi kúrò,wọ́n sì la ọ̀nà ìparun sílẹ̀ fún mi.

13. Wọ́n dínà mọ́ mi,wọ́n dá kún wahala mi,kò sì sí ẹni tí ó lè dá wọn lẹ́kun.

14. Wọ́n jálù mí, bí ìgbà tí ọpọlọpọ ọmọ ogun bá gba ihò ara odi ìlú wọlé,wọ́n ya lù mí, wọ́n wó mi mọ́lẹ̀.

15. Ìbẹ̀rù-bojo dé bá mi,wọ́n ń lépa ọlá mi bí afẹ́fẹ́,ọlà mi sì parẹ́ bí ìkùukùu.

16. “Nisinsinyii, ẹ̀mí mi fò lọ ninu mi,ọjọ́ ìjìyà sì dé bá mi.

17. Ní òru, egungun ń ro mí,ìrora mi kò sì dínkù.

18. Ọlọrun fi ipá gba aṣọ mi,ó fún mi lọ́rùn bí ọrùn ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ mi.

19. Ó sọ mí sinu ẹrẹ̀,mo dàbí eruku ati eérú.

20. “Mo ké pè ọ́, Ọlọrun, O kò dáhùn,mo dìde dúró, mo gbadura, o kò kà mí sí.

21. O dojú ibinu kọ mí,o fi agbára rẹ bá mi jà.

22. O sọ mí sókè ninu afẹ́fẹ́,ò ń bì mí síhìn-ín sọ́hùn-únláàrin ariwo ìjì líle.

23. Dájúdájú mo mọ̀ pé o óo gbé mi lọ sí ipò òkú,ilé tí o yàn fún gbogbo eniyan.

24. Bí ẹni tí a ti là mọ́lẹ̀, tí kò lè dìde, bá ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ ninu ìnira,dájúdájú o kò tún ní gbé ìjà kò ó?

25. Ṣebí mo ti sọkún nítorí àwọn tí wọ́n wà ninu ìṣòro rí,tí mo sì káàánú àwọn aláìní.

26. Ṣugbọn nígbà tí mo bá ń retí ohun rere,ibi ní ń bá mi.Nígbà tí mo bá sì ń retí ìmọ́lẹ̀,òkùnkùn ni mò ń rí.

27. Ọkàn mi dàrú, ara mi kò balẹ̀,ọjọ́ ìpọ́njú dé bá mi.

28. Mo fa ojú ro, mò ń káàkiri,mo dìde nàró láti bèèrè ìrànlọ́wọ́ láàrin àwùjọ.

29. Mò ń kígbe arò bí ajáko,mo di ẹgbẹ́ ẹyẹ ògòǹgò.

30. Àwọ̀ ara mi di dúdú, ó ń bó,egungun mi gbóná fún ooru.

31. Ọ̀fọ̀ dípò orin ayọ̀ fún mi,ẹkún sì dípò ohùn fèrè.

Jobu 30