Jobu 30:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Ṣugbọn nisinsinyii àwọn tí wọ́n kéré sí mi ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà,àwọn tí baba wọn kò tó fi wé àwọn ajátí ń ṣọ́ agbo ẹran mi.

2. Kí ni anfaani agbára wọn fún mi,àwọn tí wọn kò lókun ninu?

3. Ninu ìyà ati ebi,wọ́n ń jẹ gbòǹgbò igi gbígbẹ káàkiri lálẹ́ ninu aṣálẹ̀.

4. Ewé igi inú igbó ni wọ́n ń já jẹ,àní, àwọn igi ọwọ̀ tí kò ládùn kankan.

5. Wọ́n lé wọn jáde láàrin àwọn eniyan,wọ́n ń hó lé wọn lórí bí olè.

6. Wọ́n níláti máa gbé ojú àgbàrá,ninu ihò ilẹ̀, ati ihò àpáta.

7. Wọ́n ń dún bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ninu igbó,wọ́n ń kó ara wọn jọ sí abẹ́ igi ẹlẹ́gùn-ún.

8. Àwọn aláìlóye ọmọ,àwọn ọmọ eniyan lásán,àwọn tí a ti nà kúrò lórí ilẹ̀ náà.

9. “Nisinsinyii mo ti di orin lẹ́nu wọn,mo ti di àmúpòwe.

10. Mo di ẹni ìríra lọ́dọ̀ wọn,wọ́n ń rí mi sá,ara kò tì wọ́n láti tutọ́ sí mi lójú.

11. Nítorí Ọlọrun ti sọ mí di aláìlera,ó sì ti rẹ̀ mí sílẹ̀,wọn dojú ìjà kọ mí ninu ibinu wọn.

12. Àwọn oníjàgídíjàgan dìde sí mi ní apá ọ̀tún mi,wọ́n lé mi kúrò,wọ́n sì la ọ̀nà ìparun sílẹ̀ fún mi.

Jobu 30