1. “Ṣugbọn nisinsinyii àwọn tí wọ́n kéré sí mi ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà,àwọn tí baba wọn kò tó fi wé àwọn ajátí ń ṣọ́ agbo ẹran mi.
2. Kí ni anfaani agbára wọn fún mi,àwọn tí wọn kò lókun ninu?
3. Ninu ìyà ati ebi,wọ́n ń jẹ gbòǹgbò igi gbígbẹ káàkiri lálẹ́ ninu aṣálẹ̀.
4. Ewé igi inú igbó ni wọ́n ń já jẹ,àní, àwọn igi ọwọ̀ tí kò ládùn kankan.
5. Wọ́n lé wọn jáde láàrin àwọn eniyan,wọ́n ń hó lé wọn lórí bí olè.
6. Wọ́n níláti máa gbé ojú àgbàrá,ninu ihò ilẹ̀, ati ihò àpáta.
7. Wọ́n ń dún bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ninu igbó,wọ́n ń kó ara wọn jọ sí abẹ́ igi ẹlẹ́gùn-ún.
8. Àwọn aláìlóye ọmọ,àwọn ọmọ eniyan lásán,àwọn tí a ti nà kúrò lórí ilẹ̀ náà.
9. “Nisinsinyii mo ti di orin lẹ́nu wọn,mo ti di àmúpòwe.
10. Mo di ẹni ìríra lọ́dọ̀ wọn,wọ́n ń rí mi sá,ara kò tì wọ́n láti tutọ́ sí mi lójú.