Jobu 29:7-14 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Nígbà tí mo lọ sí ẹnubodè ìlú,tí mo jókòó ní gbàgede,

8. tí àwọn ọdọmọkunrin bá rí mi, wọn á bìlà sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan,àwọn àgbà á sì dìde dúró;

9. àwọn ìjòyè á dákẹ́ rọ́rọ́,wọn á fi ọwọ́ bo ẹnu wọn.

10. Àwọn olórí á panumọ́,ahọ́n wọn á lẹ̀ mọ́ wọn lẹ́nu.

11. Àwọn tí wọ́n gbọ́ nípa mi, ń pè mí ní ẹni ibukun,àwọn tí wọ́n rí mi ń kan sáárá sí mi.

12. Nítorí pé mò ń ran àwọn aláìní tí ń ké lọ́wọ́,ati àwọn aláìníbaba tí wọn kò ní olùrànlọ́wọ́.

13. Ìre àwọn tí ń kú lọ mọ́ mi,mo sì mú kí opó kọrin ayọ̀.

14. Mo fi òdodo bora bí aṣọ,ìdájọ́ òtítọ́ dàbí ẹ̀wù ati adé mi.

Jobu 29