Jobu 29:13-17 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Ìre àwọn tí ń kú lọ mọ́ mi,mo sì mú kí opó kọrin ayọ̀.

14. Mo fi òdodo bora bí aṣọ,ìdájọ́ òtítọ́ dàbí ẹ̀wù ati adé mi.

15. Mo jẹ́ ojú fún afọ́jú,ati ẹsẹ̀ fún arọ.

16. Mo jẹ́ baba fún talaka,mo gba ẹjọ́ àlejò rò.

17. Mo ṣẹ́ ẹni ibi lápá,mo gba ẹni tí ó mú sílẹ̀.

Jobu 29