Jobu 24:2-7 BIBELI MIMỌ (BM)

2. “Àwọn eniyan a máa hú òkúta ààlà kúrò,láti gba ilẹ̀ ẹlòmíràn kún tiwọn,wọn a máa fi ipá sọ agbo ẹran ẹlòmíràn di tiwọn.

3. Wọn a kó kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláìníbaba lọ,wọn a gba akọ mààlúù opó gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò.

4. Wọn a ti àwọn aláìní kúrò lójú ọ̀nà,gbogbo àwọn talaka a sì lọ sápamọ́.

5. “Àwọn aláìní a máa ṣe làálàá káàkiri,bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ inú aṣálẹ̀,wọn a máa wá oúnjẹ fún àwọn ọmọ wọn ninu aṣálẹ̀.

6. Wọn a máa kó oúnjẹ jọ fún ẹran wọn ninu oko olókowọn a sì máa he èso àjàrà ní oko ìkà.

7. Wọn a máa sùn ní ìhòòhò ní gbogbo òru,wọn kìí sìí rí aṣọ fi bora nígbà òtútù.

Jobu 24