Jobu 20:1-8 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Sofari, ará Naama bá dáhùn pé,

2. “Lọ́kàn mi, mo fẹ́ fèsì sí ọ̀rọ̀ rẹ,ara sì ń wá mi, bí ẹni pé kí n dá ọ lóhùn.

3. Mo gbọ́ èébú tí o bú mi,mo sì mọ irú èsì tí ó yẹ kí n fọ̀.

4. Ṣé o kò mọ̀ bẹ́ẹ̀ láti ìgbà àtijọ́,láti ìgbà tí wọ́n ti dá eniyan sórí ilẹ̀ ayé,

5. pé bí inú eniyan burúkú bá ń dùn,tí ẹni tí kò mọ Ọlọrun bá ń yọ̀, fún ìgbà díẹ̀ ni.

6. Bí ìgbéraga rẹ̀ tilẹ̀ ga, tí ó kan ọ̀run,tí orí rẹ̀ kan sánmà,

7. yóo ṣòfò títí lae bí ìgbọ̀nsẹ̀ ara rẹ̀,àwọn tí wọ́n mọ̀ ọ́n yóo bèèrè pé, ‘Níbo ló wà?’

8. Yóo parẹ́ bí àlá,yóo sì di àwátì,yóo pòórá bí ìran tí a rí lóru.

Jobu 20