1. Nígbà tí ó tún yá tí àwọn ọmọ Ọlọrun wá farahàn níwájú OLUWA, Satani náà wà láàrin wọn.
2. OLUWA tún bi Satani pé, “Níbo ni o ti ń bọ̀?”Satani dá OLUWA lóhùn pé, “Mò ń lọ sókè sódò káàkiri gbogbo ayé.”
3. Ọlọrun tún bi í pé, “Ǹjẹ́ o ṣàkíyèsí Jobu, iranṣẹ mi, pé kò sí olóòótọ́ ati eniyan rere bíi rẹ̀ ní gbogbo ayé. Ó bẹ̀rù OLUWA, ó sì kórìíra ìwà burúkú, ó dúró ṣinṣin ninu ìwà òtítọ́ rẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o dẹ mí sí i láti pa á run láìnídìí.”
4. Satani dá OLUWA lóhùn pé, “Ohun gbogbo ni eniyan lè fi sílẹ̀ láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là.
5. Ìwọ fi ọwọ́ kan ara ati eegun rẹ̀ wò, bí kò bá ní sọ̀rọ̀ àfojúdi sí ọ lójú ara rẹ.”