Jobu 14:9-18 BIBELI MIMỌ (BM)

9. bí ó bá ti gbóòórùn omi, yóo sọ,yóo sì yọ ẹ̀ka bí ọ̀dọ́ irúgbìn.

10. Ṣugbọn bí eniyan bá kú, a óo tẹ́ ẹ sinu ibojì,bí ó bá ti gbẹ́mìí mì, ó di aláìsí.

11. Bí adágún omi tíí gbẹ,ati bí odò tíí ṣàn lọ, tí sìí gbẹ,

12. bẹ́ẹ̀ ni eniyan ṣe é sùn,tí kì í sìí jí mọ́,títí tí ọ̀run yóo fi kọjá lọ, kò ní jí,tabi kí ó tilẹ̀ rúnra láti ojú oorun.

13. Ìbá sàn kí o fi mí pamọ́ sinu ibojì,kí o pa mí mọ́ títí inú rẹ yóo fi rọ̀,ò bá dá àkókò fún mi, kí o sì ranti mi.

14. Bí eniyan bá kú, ǹjẹ́ yóo tún jí mọ́?N óo dúró ní gbogbo ọjọ́ làálàá mi,n óo máa retí, títí ọjọ́ ìdáǹdè mi yóo fi dé.

15. O óo pè mí, n ó sì dá ọ lóhùn,o óo máa ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

16. Nígbà náà, o óo máa tọ́ ìṣísẹ̀ mi,o kò sì ní ṣọ́ àwọn àṣìṣe mi.

17. O óo di àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi sinu àpò,o óo sì bo àwọn àìdára mi mọ́lẹ̀.

18. “Ṣugbọn òkè ńlá ṣubú, ó sì rún wómúwómú,a sì ṣí àpáta nídìí kúrò ní ipò rẹ̀.

Jobu 14