Jobu 12:7-12 BIBELI MIMỌ (BM)

7. “Ṣugbọn, bèèrè lọ́wọ́ àwọn ẹranko, wọn óo sì kọ́ ọ,bi àwọn ẹyẹ, wọn yóo sì sọ fún ọ;

8. tabi kí o bi àwọn koríko, wọn yóo sì kọ́ ọ,àwọn ẹja inú òkun yóo sì ṣe àlàyé fún ọ.

9. Ta ni kò mọ̀ ninu gbogbo wọnpé OLUWA ló ṣe èyí?

10. Ọwọ́ rẹ̀ ni ìyè gbogbo ẹ̀dá wà,ati ẹ̀mí gbogbo eniyan.

11. Ṣebí etí a máa dán ọ̀rọ̀ wò,ahọ́n a sì máa tọ́ oúnjẹ wò?

12. “Àgbà ló ni ọgbọ́n,àwọn ogbó tí wọ́n ti pẹ́ láyé ni wọ́n ni òye.

Jobu 12