1. Sofari ará Naama dáhùn pé,
2. “Ǹjẹ́ ó dára kí eniyan sọ ọpọlọpọ ọ̀rọ̀ kalẹ̀ báyìí kí ó má sì ìdáhùn?Àbí, ṣé ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ lè mú kí á dá eniyan láre?
3. Ṣé o rò pé ìsọkúsọ rẹ lè pa eniyan lẹ́nu mọ́ ni?Tabi pé bí o bá ń ṣe ẹlẹ́yà ẹnikẹ́ni kò lè dójútì ọ́?
4. Nítorí o sọ pé ẹ̀kọ́ rẹ tọ̀nà,ati pé ẹni mímọ́ ni ọ́ lójú Ọlọrun.
5. Ọlọrun ìbá ya ẹnu rẹ̀,kí ó sọ̀rọ̀ sí ọ.
6. Kì bá jẹ́ fi àṣírí ọgbọ́n hàn ọ́,nítorí ìmọ̀ rẹ̀ pọ̀ lọpọlọpọ.Mọ̀ dájú pé ìyà tí Ọlọrun fi jẹ ọ́kò to nǹkan lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.
7. “Ǹjẹ́ o lè wádìí àwọn ohun ìjìnlẹ̀ nípa Ọlọrun?Tabi kí o tọpinpin Olodumare?
8. Ó ga ju ọ̀run lọ, kí lo lè ṣe sí i?Ó jìn ju isà òkú lọ, kí lo lè mọ̀ nípa rẹ̀?
9. Ó gùn ju ayé lọ,Ó sì fẹ̀ ju òkun lọ.