1. “Tó bá di ìgbà náà, wọn yóo kó egungun àwọn ọba Juda jáde kúrò ninu ibojì wọn, ati egungun àwọn ìjòyè ibẹ̀; ati ti àwọn alufaa, ati ti àwọn wolii, ati ti àwọn ará Jerusalẹmu.
2. Wọn óo fọ́n wọn dà sílẹ̀ ninu oòrùn, ati lábẹ́ òṣùpá ati àwọn ìràwọ̀ tí wọ́n ní ìfẹ́ sí, tí wọ́n sì sìn; àwọn ohun tí wọn ń wá kiri, tí wọn ń ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ wọn, tí wọ́n sì ń bọ. A kò ní kó egungun wọn jọ, bẹ́ẹ̀ ni a kò ní sin wọ́n. Wọn óo dàbí ìgbọ̀nsẹ̀ lórí ilẹ̀.
3. Yóo sàn kí àwọn tí ó bá kù ninu ìran burúkú yìí kú ju kí wọ́n wà láàyè lọ, ní ibikíbi tí mo bá lé wọn lọ. Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
4. OLUWA ní kí n sọ fún wọn pé,“Ṣé bí eniyan bá ṣubúkì í tún dìde mọ́?Àbí bí eniyan bá ṣìnà,kì í pada mọ́?
5. Kí ló dé tí àwọn eniyan wọnyi fi yipadakúrò lọ́dọ̀ mi,tí wọn ń lọ láì bojúwẹ̀yìn?Ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn ni wọ́n sì wawọ́ mọ́;wọ́n kọ̀, wọn kò pada sọ́dọ̀ mi.
6. Mo tẹ́tí sílẹ̀ kí n gbọ́ tiwọn,ṣugbọn wọn kò sọ̀rọ̀ rere.Kò sí ẹni tí ó kẹ́dùn iṣẹ́ ibi rẹ̀,kí ó wí pé, ‘Kí ni mo ṣe yìí?’Olukuluku tẹ̀ sí ọ̀nà tí ó wù ú,bí ẹṣin tí ń sáré lọ ojú ogun.
7. Ẹyẹ àkọ̀ tí ń fò lójú ọ̀run pàápàá mọ àkókò rẹ̀.Bẹ́ẹ̀ sì ni àdàbà, ati lékèélékèé, ati alápàáǹdẹ̀dẹ̀;wọ́n mọ àkókò tí ó yẹ láti ṣípò pada.Ṣugbọn àwọn eniyan mi kò mọ òfin OLUWA.
8. Báwo ni ẹ ṣe lè wí pé,‘Ọlọ́gbọ́n ni wá,a sì mọ òfin OLUWA?’Ṣugbọn àwọn akọ̀wé ti fi gègé irọ́ wọn sọ ọ́ di èké.
9. Ojú yóo ti àwọn ọlọ́gbọ́n:ìdààmú yóo bá wọn,ọwọ́ yóo sì tẹ̀ wọ́n.Wò ó! Wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ OLUWA sílẹ̀,ọgbọ́n wo ni ó kù tí wọ́n gbọ́n?
10. Nítorí náà, n óo fi aya wọn fún ẹlòmíràn,n óo fi oko wọn fún àwọn tí yóo ṣẹgun wọn.Nítorí pé láti orí àwọn mẹ̀kúnnù,títí dé orí àwọn eniyan pataki pataki,gbogbo wọn ni wọ́n ń lépa èrè àjẹjù.Láti orí wolii títí kan alufaa, èké ni gbogbo wọn.
11. Wọn kò wẹ egbò àwọn eniyan mi jinná,wọ́n ń kígbe pé, ‘Alaafia ni, alaafia ni,’bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí alaafia.