57. N óo jẹ́ kí àwọn ìjòyè rẹ̀ ati àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀ mu ọtí ní àmuyó,pẹlu àwọn gomina rẹ̀, àwọn ọ̀gágun rẹ̀, ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀.Wọn yóo sun oorun àsùnrayè,wọn kò sì ní jí mọ́ laelae.Bẹ́ẹ̀ ni èmi ọba, tí orúkọ mi ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ.
58. Odi Babiloni tí ó fẹ̀, yóo wó lulẹ̀,a óo sì dáná sun àwọn ẹnubodè rẹ̀ tí ó ga fíofío.Iṣẹ́ lásán ni àwọn eniyan ń ṣe,àwọn orílẹ̀-èdè sì ń yọ ara wọn lẹ́nu lásán ni,nítorí pé iná yóo jó gbogbo làálàá wọn.”
59. Jeremaya wolii pa àṣẹ kan fún Seraaya, alabojuto ibùdó ogun, ọmọ Neraya, ọmọ Mahiseaya nígbà tí ó ń bá Sedekaya ọba Juda lọ sí Babiloni ní ọdún kẹrin ìjọba Sedekaya.
60. Jeremaya kọ gbogbo nǹkan burúkú tí yóo ṣẹlẹ̀ sí Babiloni ati gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ tí ó sọ nípa rẹ̀ sinu ìwé kan.
61. Ó bá pàṣẹ fún Seraaya pé nígbà tí ó bá dé Babiloni, kí ó rí i dájú pé ó ka gbogbo ohun tí òun kọ sinu ìwé náà sókè.
62. Kí ó sọ pé, “OLUWA, o ti sọ pé o óo pa ibí yìí run, tóbẹ́ẹ̀ tí kò fi ní sí nǹkankan tí yóo máa gbé inú rẹ̀ mọ́, ìbáà ṣe eniyan tabi ẹranko. O ní títí lae ni yóo di ahoro.”
63. Jeremaya ní nígbà tí Seraaya bá ka ìwé yìí tán, kí ó di òkúta kan mọ́ ọn kí ó jù ú sí ààrin odò Yufurate,
64. kí ó sì sọ wí pé, “Báyìí ni yóo rí fún Babiloni, kò sì ní gbérí mọ́, nítorí ibi tí OLUWA yóo mú kí ó dé bá a.”Ibí yìí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Jeremaya sọ parí sí.