Jeremaya 51:43-57 BIBELI MIMỌ (BM)

43. Àwọn ìlú rẹ̀ ti di àríbẹ̀rù,wọ́n ti di ilẹ̀ gbígbẹ ati aṣálẹ̀,ilẹ̀ tí ẹnikẹ́ni kò gbé mọ́,tí ọmọ eniyan kò sì gbà kọjá mọ́.

44. N óo fìyà jẹ oriṣa Bẹli ní Babiloni,n óo jẹ́ kí ó pọ ohun tí ó gbé mì.Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ mọ́,odi Babiloni pàápàá yóo wó lulẹ̀.

45. “Ẹ̀yin eniyan mi, ẹ jáde kúrò níbẹ̀!Kí olukuluku sá àsálà, kúrò lọ́wọ́ ibinu gbígbóná OLUWA!

46. Ẹ mọ́kàn, ẹ má bẹ̀rù,nítorí ìròyìn tí ẹ̀ ń gbọ́ nípa ilẹ̀ náà,nígbà tí ẹ bá gbọ́ ìròyìn kan ní ọdún yìí,tí ẹ tún gbọ́ òmíràn ní ọdún tí ń bọ̀,tí ìwà ipá sì wà ní ilẹ̀ náà,tí àwọn ìjòyè sì ń dojú ìjà kọ ara wọn.

47. Nítorí náà, wò ó, ọjọ́ ń bọ̀tí n óo fìyà jẹ àwọn ère ilẹ̀ Babiloni.Ojú yóo ti gbogbo ilẹ̀ rẹ̀,òkú àwọn eniyan rẹ̀ tí ogun yóo pa,yóo wà nílẹ̀ káàkiri ìgboro.

48. Nítorí náà, ọ̀run ati ayé, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn,yóo yọ̀ nítorí ìṣubú Babiloni,nítorí pé apanirun yóo wá gbógun tì í, láti ìhà àríwá,Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

49. Bí àwọn tí ogun Babiloni pa ní àwọn orílẹ̀-èdè ayé,ti ṣubú níwájú rẹ̀.Bẹ́ẹ̀ ni Babiloni náà gbọdọ̀ ṣubú,nítorí àwọn tí wọ́n pa ní Israẹli.”

50. OLUWA sọ fún àwọn eniyan rẹ̀ ní Babiloni pé,“Ẹ̀yin tí ẹ bọ́ lọ́wọ́ idà,ẹ má dúró, ẹ máa sálọ!Ẹ ranti OLUWA ní ilẹ̀ òkèèrè,kí ẹ sì máa ronú nípa Jerusalẹmu pẹlu.

51. Ẹ̀ ń sọ pé ojú ń tì yín nítorí pé wọ́n kẹ́gàn yín;ẹ ní ìtìjú dà bò yín,nítorí pé àwọn àjèjì ti wọ ibi mímọ́ ilé OLUWA.

52. Nítorí náà, èmi OLUWA ń sọ nisinsinyii pé,ọjọ́ ń bọ̀, tí n óo ṣe ìdájọ́ lórí àwọn ère rẹ̀;àwọn tí wọ́n fara gbọgbẹ́ yóo máa kérora,ní gbogbo ilẹ̀ rẹ̀.

53. Bí Babiloni tilẹ̀ ga tí ó kan ojú ọ̀run,tí ó sì mọ odi yí àwọn ibi ààbò rẹ̀ gíga ká,sibẹsibẹ n óo rán apanirun sí i.Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

54. OLUWA ní,“Ẹ gbọ́ igbe kan láti Babiloni!Igbe ìparun ńlá láti ilẹ̀ àwọn ará Kalidea!

55. Nítorí OLUWA ń wó Babiloni lulẹ̀,ó sì ń pa á lẹ́nu mọ́.Igbe wọn ta sókè bíi híhó omi òkun ńlá

56. nítorí pé apanirun ti dé sí i,àní ó ti dé sí Babiloni.Ogun ti kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀,àwọn ọ̀tá ti rún àwọn ọfà rẹ̀ jégéjégé,nítorí pé Ọlọrun ẹ̀san ni èmi OLUWA,dájúdájú n óo gbẹ̀san.

57. N óo jẹ́ kí àwọn ìjòyè rẹ̀ ati àwọn ọlọ́gbọ́n rẹ̀ mu ọtí ní àmuyó,pẹlu àwọn gomina rẹ̀, àwọn ọ̀gágun rẹ̀, ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀.Wọn yóo sun oorun àsùnrayè,wọn kò sì ní jí mọ́ laelae.Bẹ́ẹ̀ ni èmi ọba, tí orúkọ mi ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ.

Jeremaya 51