30. Àwọn ọmọ ogun Babiloni ti ṣíwọ́ ogun jíjà,wọ́n wà ní ibi ààbò wọn;àárẹ̀ ti mú wọn, wọ́n sì ti di obinrin.Àwọn ilé inú rẹ̀ ti ń jóná,àwọn ọ̀pá ìdábùú ìlẹ̀kùn bodè rẹ̀ sì ti ṣẹ́.
31. Àwọn tí ń sáré ń pàdé ara wọn lọ́nà,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ikọ̀ ń pàdé ara wọn,bí wọ́n ti ń sáré lọ sọ fún ọba Babiloni pé ogun ti gba ìlú rẹ̀ patapata.
32. Wọ́n ti gba ibi ìsọdá odò,wọ́n ti dáná sun àwọn ibi ààbò,ìbẹ̀rùbojo sì ti mú àwọn ọmọ ogun.
33. Babiloni dàbí ibi ìpakà, tí a tẹ̀ mọ́lẹ̀ nígbà tí à ń pa ọkà.Láìpẹ́ ọ̀tá yóo dà á wó, yóo sì di àtẹ̀mọ́lẹ̀.Èmi OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
34. “Nebukadinesari ọba Babiloni ti run Jerusalẹmu,ó ti tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀,ó ti sọ ọ́ di ohun èlò òfìfo,ó gbé e mì bí erinmi,ó ti kó gbogbo ohun àdídùn inú rẹ̀ jẹ ní àjẹrankùn,ó ti da ìyókù nù.
35. Jẹ́ kí àwọn tí ń gbé Sioni wí pé,‘Kí ibi tí àwọn ará Babiloni ṣe sí wa ati sí àwọn arakunrin wa dà lé wọn lórí.’Kí àwọn ará Jerusalẹmu sì wí pé,‘Ẹ̀jẹ̀ wa ń bẹ lórí àwọn ará ilẹ̀ Kalidea.’ ”
36. Nítorí náà, OLUWA sọ fún àwọn ará Jerusalẹmu pé,“Ẹ wò ó, n óo gba ẹjọ́ yín rò,n óo sì ba yín gbẹ̀san.N óo jẹ́ kí omi òkun Babiloni gbẹ,n óo sì jẹ́ kí orísun odò rẹ̀ gbẹ.