OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “À ń ni àwọn ọmọ Israẹli lára, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ Juda; gbogbo àwọn tí wọ́n kó wọn ní ìgbèkùn ni wọ́n wo ọwọ́ mọ́ wọn, wọn kò jẹ́ kí wọn lọ.