Nítorí ibinu gbígbóná OLUWA,ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀ mọ́;yóo di ahoro patapata;ẹnu yóo ya gbogbo ẹni tí ó bá gba Babiloni kọjá,wọn yóo sì máa pòṣé nítorí ìyà tí a fi jẹ ẹ́.