1. Ọ̀rọ̀ tí OLUWA bá Jeremaya wolii sọ nípa àwọn orílẹ̀-èdè nìyí.
2. Ọ̀rọ̀ lórí Ijipti: Nípa àwọn ọmọ ogun Farao Neko, ọba Ijipti, tí wọ́n wà létí odò Yufurate ní Kakemiṣi, àwọn tí Nebukadinesari, ọba Babiloni, ṣẹgun ní ọdún kẹrin tí Jehoiakimu ọmọ Josaya jọba Juda.
3. “Ọ̀gágun Ijipti pàṣẹ fún àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pé,‘Ẹ tọ́jú asà ati apata,kí ẹ sì jáde sójú ogun!
4. Ẹ̀yin ẹlẹ́ṣin, ẹ di ẹṣin yín ní gàárì, kí ẹ sì gùn wọ́n.Ẹ dúró ní ipò yín, pẹlu àṣíborí lórí yín.Ẹ pọ́n àwọn ọ̀kọ̀ yín,kí ẹ gbé ihamọra irin yín wọ̀!’ ”
5. Oluwa ní, “Kí ni mo rí yìí?Ẹ̀rù ń bà wọ́n, wọ́n sì ń pada sẹ́yìn.A ti lu àwọn ọmọ ogun wọn bolẹ̀,wọ́n sì ń sálọ pẹlu ìkánjú;wọn kò bojú wẹ̀yìn, ìpayà yí wọn ká!
6. Àwọn tí ẹsẹ̀ wọn yá nílẹ̀ kò lè sálọ,bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ ogun kò lè sá àsálà.Ìhà àríwá, lẹ́bàá odò Yufurate, ni wọ́n tí fẹsẹ̀ kọ, tí wọ́n sì ṣubú.