1. Ní oṣù kẹwaa, ọdún kẹsan-an ìjọba Sedekaya, ọba Juda, Nebukadinesari, ọba Babiloni, ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ gbógun ti Jerusalẹmu, wọ́n sì dótì í.
2. Ní ọjọ́ kẹsan-an, oṣù kẹrin, ọdún kọkanla ìjọba rẹ̀, wọ́n wọ ìlú náà.
3. Lẹ́yìn tí ogun ti kó Jerusalẹmu, gbogbo àwọn ìjòyè ọba Babiloni péjọ, wọ́n sì jókòó ní bodè ààrin: Negali Sareseri, Samgari Nebo, Sarisekimu Rabusarisi, Negali Sareseri, Rabumagi ati àwọn ìjòyè ọba Babiloni yòókù.
4. Nígbà tí Sedekaya ọba Juda ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ rí wọn, wọ́n sá. Wọ́n fòru bojú, wọ́n bá jáde ní ìlú; wọ́n gba ọ̀nà ọgbà ọba, ní ọ̀nà ibodè tí ó wà láàrin odi meji, wọ́n sì dojú kọ ọ̀nà Araba.