1. Nígbà tí Ṣefataya, ọmọ Matani, ati Gedalaya, ọmọ Paṣuri, ati Jukali, ọmọ Ṣelemaya, ati Paṣuri ọmọ Malikaya gbọ́ ọ̀rọ̀ tí Jeremaya ń sọ fún gbogbo àwọn eniyan pé,
2. “OLUWA ní, ẹni tí ó bá dúró ní ìlú Jerusalẹmu yóo kú ikú idà, ìyàn ati àjàkálẹ̀ àrùn; ṣugbọn àwọn tí wọn bá jáde tọ àwọn ará Kalidea lọ yóo yè. Ó ní ọ̀rọ̀ wọn yóo dàbí ẹni tí ó ja àjàbọ́, ṣugbọn yóo wà láàyè.
3. Ati pé dájúdájú, ìlú yìí yóo bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun Babiloni, wọn yóo sì gbà á.”